IṢẸ SÍLÉBÙ OLÓHÙN ÀÁRÍN INÚ ÀPÓLÀ ONÍBÀÁTAN NÍNÚ ẸKA-ÈDÈ GÚSÙ-MỌ-ÌLÀ-OÒRÙN YORÙBÁ (Mid-toned Syllable in the SEY Dialects)

Ọ̀pọ̀ onímọ̀ èdè Yorùbá ni àkíyèsi ìfarahàn iṣẹ́ sílébù olóhùn òkè hàn sí kedere àmọ́ àwọn díẹ̀ ni àkíyèsi ìfarahàn iṣẹ́ sílébù olóhùn àárín inú àpólà oníbàátan hàn sí. Èrò méjì ló wà lóri iṣẹ́ fáwẹ́lí olóhùn àárín inú àpólà oníbàátan nínú ède Yorùbá àjùmọ̀lò; àwọn onímọ̀ kan gbà pé fáwẹ́lì olóhùn àárín ló ń fi àpólà oníbàátan hàn nínú èdè Yorùbá nígbà tí àwọn onímọ̀ kan tako èrò yìí. Ajíbóyè jẹ́ gíwá àwọn tó gbà pé fáwẹ́lì olóhùn àárín ló ń fi àpólà oníbàátan hàn nínú èdè Yorùbá nígbà tí Awóbùlú jẹ́ òpómúléró tó tako èrò yìí. Kí á máà déènà pẹnu, iṣẹ́ yìí yóò jíròrò iṣẹ́ sílébù olóhùn àárín inú àpólà oníbàátan nínú ẹ̀ka-èdè gúsù-mọ́-ìlà-oòrùn Yorùbá. Kí a ba lè rí òkodoro ẹ̀rí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ dì mú lóri iṣẹ́ sílébù olóhùn àárín inú àpólà oníbàátan nínú ẹ̀ka-èdè gúsù-mọ́-ìlà-oòrùn Yorùbá, òǹkọ̀wé gba ohùn sílẹ̀ lẹ́nu àwọn ọmọ-ìlú (abẹ́nà-ìmọ̀) tó gbọ́ àwọn àṣàyàn ẹ̀ka-èdè tí a ń ṣiṣẹ́ lé lórí náà ní àgbọ́dijú.

Iṣẹ́ yìí ṣe ìwádìí ìjìnlẹ̀ láti mọ̀ bóyá sílébù olóhùn àárín inú àpólà oníbàátan ló ń fi ìbátan hàn ní tòótọ́ nínú ẹ̀ka-èdè gúsù-mọ́-ìlà-oòrùn Yorùbá. Ìwádìí wa fìdi rẹ̀ múlẹ̀ pé sílébù olóhùn àárín inú àpólà oníbàátan ló ń fi ìbátan hàn ní tòótọ́ nínú ẹ̀ka-èdè gúsù-mọ́-ìlà-oòrùn Yorùbá. Ẹ̀ka-èdè gúsù-mọ́-ìlà-oòrùn Yorùbá mẹ́ta ni a ṣàmúlò fún iṣẹ́ yìí. Àwọn ni ẹ̀ka-èdè Ẹ̀gbá, Ìjẹ̀bú, àti Ìkálẹ̀

Ọ̀rọ̀ tó ṣe kókó: Sílébù olóhùn àárín (SOA), Àpólà oníbàátan, Gúsù-mọ́-ìlà-oòrùn Yorùbá


Overall Rating

0

5 Star
(0)
4 Star
(0)
3 Star
(0)
2 Star
(0)
1 Star
(0)
APA

Adeniyi, S. (2021). IṢẸ SÍLÉBÙ OLÓHÙN ÀÁRÍN INÚ ÀPÓLÀ ONÍBÀÁTAN NÍNÚ ẸKA-ÈDÈ GÚSÙ-MỌ-ÌLÀ-OÒRÙN YORÙBÁ (Mid-toned Syllable in the SEY Dialects). Afribary. Retrieved from https://track.afribary.com/works/mid-toned-syllable-in-the-sey-dialects

MLA 8th

Adeniyi, Sakiru "IṢẸ SÍLÉBÙ OLÓHÙN ÀÁRÍN INÚ ÀPÓLÀ ONÍBÀÁTAN NÍNÚ ẸKA-ÈDÈ GÚSÙ-MỌ-ÌLÀ-OÒRÙN YORÙBÁ (Mid-toned Syllable in the SEY Dialects)" Afribary. Afribary, 06 Jul. 2021, https://track.afribary.com/works/mid-toned-syllable-in-the-sey-dialects. Accessed 24 Dec. 2024.

MLA7

Adeniyi, Sakiru . "IṢẸ SÍLÉBÙ OLÓHÙN ÀÁRÍN INÚ ÀPÓLÀ ONÍBÀÁTAN NÍNÚ ẸKA-ÈDÈ GÚSÙ-MỌ-ÌLÀ-OÒRÙN YORÙBÁ (Mid-toned Syllable in the SEY Dialects)". Afribary, Afribary, 06 Jul. 2021. Web. 24 Dec. 2024. < https://track.afribary.com/works/mid-toned-syllable-in-the-sey-dialects >.

Chicago

Adeniyi, Sakiru . "IṢẸ SÍLÉBÙ OLÓHÙN ÀÁRÍN INÚ ÀPÓLÀ ONÍBÀÁTAN NÍNÚ ẸKA-ÈDÈ GÚSÙ-MỌ-ÌLÀ-OÒRÙN YORÙBÁ (Mid-toned Syllable in the SEY Dialects)" Afribary (2021). Accessed December 24, 2024. https://track.afribary.com/works/mid-toned-syllable-in-the-sey-dialects